2 Samuel 2:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn èyí, Dafidi bèèrè lọ́wọ́ OLUWA pé, “OLUWA, ṣé kí ń lọ sí ọ̀kan ninu àwọn ìlú Juda?” OLUWA sì dá a lóhùn pé, “Lọ.” Dafidi bá tún bèèrè pé, “Ìlú wo ni kí n lọ?” OLUWA ní, “Lọ sí ìlú Heburoni.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe lẹhin eyi, Dafidi si bere lọwọ Oluwa, pe, Ki emi ki o goke lọ si ọkan ni ilu Juda wọnni bi? Oluwa si wi fun u pe, Goke lọ: Dafidi si wipe, niha ibo ni ki emi ki o lọ? On si wipe, Ni Hebroni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn àkókò yìí, Dáfídì wádìí lọ́wọ́ OLÚWA. Ó sì béèrè pé, “Ṣé èmi lè gòkè lọ sí ọ̀kan lára àwọn ìlú Júdà?” OLÚWA sì wí pé, “Gòkè lọ.” Dáfídì sì béèrè pé, “Ní ibo ni kí èmi kí ó lọ?” OLÚWA sì dáa lóhùn pé, “Sí Hébúrónì.”