2 Samuel 2:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹni ogoji ọdún ni nígbà tí wọ́n fi jọba lórí Israẹli, ó sì wà lórí oyè fún ọdún meji. Ṣugbọn ẹ̀yìn Dafidi ni gbogbo ẹ̀yà Juda wà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iṣboṣeti ọmọ Saulu si jẹ ẹni ogoji ọdun nigbati o bẹrẹ si ijọba lori Israeli, o si jọba li ọdun meji. Ṣugbọn idile Juda ntọ̀ Dafidi lẹhin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Íṣíbóṣétì ọmọ Ṣọ́ọ̀lù sì jẹ́ ọmọ ogójì ọdún nígbà tí ó jẹ ọba lórí Ísírẹ́lì, ó sì jọba fún ọdún méjì. Ilé Júdà sì ń tọ Dáfídì lẹ́yìn.