2 Samuel 2:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Abineri bá sọ fún Joabu pé, “Jẹ́ kí àwọn bíi mélòó kan ninu àwọn ọmọkunrin láti ẹ̀gbẹ́ kinni keji bọ́ siwaju, kí wọ́n fi ohun ìjà dánrawò níwájú wa.” Joabu sì gbà bẹ́ẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Abneri si wi fun Joabu pe, Jẹ ki awọn ọmọkunrin dide nisisiyi, ki nwọn ki o si ta pọrọ́ niwaju wa. Joabu si wipe, Jẹ ki wọn ki o dide.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà, Ábínérì sọ fún Jóábù pé, “Jẹ́ kí díẹ̀ nínú àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yìí ó dìde láti bá ara wọn jà níwájú wa.” Jóábù sì dáhùn pé, “Ó dára, jẹ́ kí wọ́n ṣe é,”