2 Samuel 2:29 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gbogbo òru ọjọ́ náà ni Abineri ati àwọn eniyan rẹ̀ fi ń rìn pada lọ ní àfonífojì Jọdani, wọ́n kọjá sí òdìkejì odò Jọdani. Gbogbo òwúrọ̀ ọjọ́ keji ni wọ́n sì fi rìn kí wọ́n tó pada dé Mahanaimu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Abneri ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si fi gbogbo oru na rìn ni pẹtẹlẹ, nwọn si kọja Jordani, nwọn si rìn ni gbogbo Bitroni, nwọn si wá si Mahanaimu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ábínérì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì fi gbogbo òru náà rìn ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n sì kọjá Jọ́dánì, wọ́n sì rìn ní gbogbo Bítírónì, wọ́n sì wá sí Mahanáímù.