2 Samuel 2:32 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Joabu ati àwọn eniyan rẹ̀ bá gbé òkú Asaheli, wọ́n sì lọ sin ín sí ibojì ìdílé wọn ní Bẹtilẹhẹmu. Gbogbo òru ọjọ́ náà ni wọ́n fi rìn; ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, ni wọ́n pada dé Heburoni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si gbe Asaheli, nwọn si sin i sinu ibojì baba rẹ̀ ti o wà ni Betlehemu. Joabu ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ fi gbogbo oru na rin, ilẹ si mọ́ wọn si Hebroni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n si gbé Ásáhélì wọ́n sì sinín sínú ibojì baba rẹ̀ tí ó wà ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Jóábù àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ fi gbogbo òru náà rìn, ilẹ̀ sì mọ́ wọn sí Hébírónì.