2 Samuel 20:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Aláìníláárí ẹ̀dá kan wà ní ààrin àwọn ará Giligali tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ṣeba, ọmọ Bikiri, láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini. Ọkunrin yìí fọn fèrè, ó ní, “Kò sí ohun tí ó kàn wá pẹlu Dafidi, a kò sì ní ìpín nílé ọmọ Jese. Ẹ pada sí ilé yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọkunrin Beliali kan si mbẹ nibẹ orukọ rẹ̀ si njẹ Ṣeba ọmọ Bikri ara Benjamini; o si fún ipè o si wipe, Awa kò ni ipa ni Dafidi, bẹ̃li awa kò ni ini ni ọmọ Jesse: ki olukuluku ọkunrin lọ si agọ rẹ̀, ẹnyin Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọkùnrin Bélíálì kan sì ń bẹ níbẹ̀ orúkọ rẹ̀ sì ń jẹ́ Ṣébà ọmọ Bíkírì ará Bẹ́ńjámínì; ó sì fún ìpè ó sì wí pé, “Àwa kò ní ipa nínú Dáfídì, bẹ́ẹ̀ ni àwa kò ni ìní nínú ọmọ Jésè! Kí olúkúlùkù ọkùnrin lọ sí àgọ́ rẹ̀, ẹ̀yin Ísírẹ́lì!”