2 Samuel 20:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Amasa kò fura rárá pé idà wà ní ọwọ́ Joabu. Joabu bá gún un ní idà níkùn, gbogbo ìfun rẹ̀ tú jáde. Amasa kú lẹsẹkẹsẹ, láì jẹ́ pé Joabu tún gún un ní idà lẹẹkeji. Joabu ati Abiṣai arakunrin rẹ̀ bá ń lépa Ṣeba lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Amasa ko si kiyesi idà ti mbẹ li ọwọ́ Joabu: bẹ̃li on si fi gun u li ẽgun ìha ikarun, ifun rẹ̀ si tú dá silẹ, on kò si tun gún u mọ́; o si kú. Joabu ati Abiṣai arakunrin rẹ̀ si lepa Ṣeba ọmọ Bikri.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n Ámásà kò sì kíyèsí idà tí ń bẹ lọ́wọ́ Jóábù: bẹ́ẹ̀ ni òun sì fi gún un ní ikùn, ìfun rẹ̀ sì tú dà sílẹ̀, òun kò sì tún gún un mọ́: ó sì kú. Jóábù àti Ábíṣáì arákùnrin rẹ̀ sì lépa Ṣébà ọmọ Bíkírì.