2 Samuel 20:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ogun Joabu dúró ti òkú Amasa, ó sì ń kígbe pé, “Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe ti Joabu ati ti Dafidi tẹ̀lé Joabu.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọkan ninu awọn ọdọmọdekunrin ti o wà lọdọ Joabu si duro tì i, o si wipe, Tali ẹni ti o ba fẹran Joabu? tali o si nṣe ti Dafidi, ki o ma tọ̀ Joabu lẹhin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọ̀kan nínú àwọn ọ̀dọ́mọdékùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ Jóábù sì dúró tì í, ó sì wí pé, “Ta ni ẹni tí ó fẹ́ràn Jóábù? Ta ni ó sì ń ṣe ti Dáfídì, kí ó máa tọ Jóábù lẹ́yìn.”