2 Samuel 20:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Òkú Amasa, tí ẹ̀jẹ̀ ti bò, wà ní ojú ọ̀nà gbangba, ẹnikẹ́ni tí ó bá ń kọjá, tí ó bá rí i ń dúró. Nígbà tí ọkunrin tí ó dúró ti òkú náà rí i pé gbogbo eniyan ní ń dúró, ó wọ́ òkú náà kúrò lójú ọ̀nà, sinu igbó, ó sì fi aṣọ bò ó.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Amasa si nyira ninu ẹ̀jẹ larin ọ̀na. ọkunrin na si ri pe gbogbo enia si duro tì i, o si gbe Amasa kuro loju ọ̀na lọ sinu ìgbẹ́, o si fi aṣọ bò o, nigbati o ti ri pe ẹnikẹni ti o ba de ọdọ rẹ̀, a duro.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ámásà sì ń yíràá nínú ẹ̀jẹ̀ láàrin ọ̀nà. Ọkùnrin náà sì ríi pé gbogbo ènìyàn sì dúró tì í, ó sì gbé Ámásà kúrò lójú ọ̀nà lọ sínú ìgbẹ́, ó sì fi aṣọ bò ó, nígbà tí ó rí i pé ẹnìkẹ́ni tí ó bá dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, á dúró.