2 Samuel 20:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ọmọ ogun Joabu bá lọ dó ti ìlú náà, wọ́n fi erùpẹ̀ mọ òkítì gíga sára odi rẹ̀ lóde, wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí gbẹ́ odi náà lábẹ́, wọ́n fẹ́ wó o lulẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn wá, nwọn si do tì i ni Abeli ti Betmaaka, nwọn si mọdi tì ilu na, odi na si duro ti odi ilu na: gbogbo enia ti mbẹ lọdọ Joabu si ngbiyanju lati wó ogiri na lulẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n wá, wọ́n sì dó tì í ní Ábélì tí Bẹti Máákà, wọ́n sì mọ odí ti ìlú náà, odi náà sì dúró ti odi ìlú náà, gbogbo ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ Jóábù sì ń gbìyànjú láti wó ògiri náà lulẹ̀.