2 Samuel 20:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Abeli jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn ìlú tí ó fẹ́ alaafia, tí ó sì jẹ́ olóòótọ́ jùlọ ní Israẹli. Ṣé o wá fẹ́ pa ìlú tí ó jẹ́ ìyá ní Israẹli run ni? Kí ló dé tí o fi fẹ́ pa nǹkan OLUWA run?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi li ọkan ninu awọn ẹni alafia ati olõtọ ni Israeli: iwọ nwá ọ̀na lati pa ilu kan run ti o jẹ iyá ni Israeli: ẽṣe ti iwọ o fi gbe ini Oluwa mì?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi ni ọ̀kan nínú àwọn ẹni àlàáfíà àti tòótọ́ ní Ísírẹ́lì: ìwọ ń wá ọ̀nà láti pa ìlú kan run tí ó jẹ́ ìyá ní Ísírẹ́lì: èéṣe tí ìwọ ó fi gbé ìní OLÚWA mì.”