2 Samuel 20:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọkunrin kan, tí ń jẹ́ Ṣeba, ọmọ Bikiri, láti agbègbè olókè ti Efuraimu, ni ó ń dìtẹ̀ mọ́ Dafidi ọba. Bí o bá ti fa òun nìkan ṣoṣo kalẹ̀, n óo kúrò ní ìlú yín.” Obinrin yìí bá dáhùn pé, “A óo ju orí rẹ̀ sílẹ̀ sí ọ, láti orí odi.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọràn na kò ri bẹ̃; ṣugbọn ọkunrin kan lati oke Efraimu, ti orukọ rẹ̀ njẹ Ṣeba, ọmọ Bikri, li o gbe ọwọ́ rẹ̀ soke si ọba, ani si Dafidi: fi on nikanṣoṣo le wa lọwọ, emi o si fi ilu silẹ. Obinrin na si wi fun Joabu pe, Wõ, ori rẹ̀ li a o si sọ si ọ lati inu odi wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọ̀ràn náà kò sì rí bẹ́ẹ̀; ṣùgbọ́n ọkùnrin kan láti òkè Éfúráímù, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ṣébà, ọmọ Bíkírì, ni ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sòkè sí ọba, àní sí Dáfídì: fi òun nìkanṣoṣo lé wa lọ́wọ́, èmi ó sì fi ìlú sílẹ̀.” Obìnrin náà sì wí fún Jóábù pé, “Wò ó, orí rẹ̀ ni a ó sì sọ láti inú odì wá.”