2 Samuel 20:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Obinrin yìí bá tọ gbogbo àwọn ará ìlú lọ, ó sì fi ọgbọ́n bá wọn sọ̀rọ̀. Wọ́n bá gé orí Ṣeba, wọ́n jù ú sí Joabu láti orí odi. Joabu bá fọn fèrè ogun, gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì fi ìlú náà sílẹ̀, wọ́n pada sí ilé. Joabu bá pada lọ sọ́dọ̀ ọba, ní Jerusalẹmu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Obinrin na si mu ìmọran rẹ̀ tọ gbogbo awọn enia na. Nwọn si bẹ́ Ṣeba ọmọ Bikri li ori, nwọn si sọ ọ si Joabu. On si fún ipè, nwọn si tuka kuro ni ilu na, olukuluku si agọ rẹ̀. Joabu si pada lọ si Jerusalemu ati sọdọ ọba.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Obìnrin náà sì mú ìmọ́ran rẹ̀ tọ gbogbo àwọn ènìyàn náà, wọ́n sì bẹ Ṣébà ọmọ Bíkírì lórí, wọ́n sì sọ ọ́ sí Jóábù. Òun sì fún ìpè, wọ́n sì túká sọ́dọ̀ ọba.