2 Samuel 20:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí Dafidi pada dé ààfin rẹ̀ ní Jerusalẹmu, ó mú àwọn obinrin rẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí ó fi sílẹ̀, pé kí wọ́n máa tọ́jú ààfin, ó fi wọ́n sinu ilé kan pẹlu olùṣọ́, ó sì ń pèsè oúnjẹ fún wọn, ṣugbọn kò bá wọn lòpọ̀ mọ́. Ninu ìhámọ́ ni wọ́n wà, tí wọ́n ń gbé bí opó, títí tí wọ́n fi kú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si wá si ile rẹ̀ ni Jerusalemu; ọba si mu awọn obinrin mẹwa ti iṣe alè rẹ̀, awọn ti o ti fi silẹ lati ma ṣọ́ ile. O si há wọn mọ ile, o si mbọ́ wọn, ṣugbọn kò si tun wọle tọ̀ wọn mọ a si se wọn mọ titi di ọjọ ikú wọn, nwọn si wà bi opo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì sì wà ní ilé rẹ̀ ní Jérúsálẹ́mù; ọba sì mú àwọn obìnrin mẹ́wàá tí í ṣe àlè rẹ̀, àwọn tí ó ti fi sílẹ̀ láti máa ṣọ́ ile, Ó sì há wọn mọ́ ilé, ó sì ń bọ́ wọn, ṣùgbọ́n kò sì tún wọlé tọ̀ wọ́n mọ́. A sì ṣé wọn mọ́ títí di ọjọ́ ikú wọn, wọ́n sì wà bí opó.