2 Samuel 20:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọba bá pe Abiṣai, ó ní, “Ìyọnu tí Ṣeba yóo kó bá wa yóo ju ti Absalomu lọ. Nítorí náà, kó àwọn eniyan mi lẹ́yìn kí o sì máa lépa rẹ̀ lọ. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ó lè gba àwọn ìlú olódi bíi mélòó kan kí ó sì dá wahala sílẹ̀ fún wa.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si wi fun Abiṣai pe, Nisisiyi Ṣeba ọmọ Bikri yio ṣe wa ni ibi jù ti Absalomu lọ; iwọ mu awọn iranṣẹ Oluwa rẹ, ki o si lepa rẹ̀, ki o ma ba ri ilu olodi wọ̀, ki o si bọ́ lọwọ wa,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì sì wí fún Ábíṣáì pé, “Nísinsinyìí Ṣébè ọmọ Bíkírì yóò ṣe wá ní ibi ju ti Ábúsálómù lọ; ìwọ mú àwọn ìránṣẹ́ olúwa rẹ, kí o sì lépa rẹ̀, kí ó má baà rí ìlú olódì wọ̀, kí ó sì bọ́ lọ́wọ́ wa.”