2 Samuel 20:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí wọ́n dé ibi òkúta ńlá kan, tí ó wà ní Gibeoni, Amasa lọ pàdé wọn. Ẹ̀wù ọmọ ogun ni Joabu wọ̀; ó sán ìgbànú kan, idà rẹ̀ sì wà ninu àkọ̀ lára ìgbànú tí ó ti sán mọ́ ìbàdí. Bí Joabu ti rìn siwaju bẹ́ẹ̀ ni idà yìí bọ́ sílẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati nwọn de ibi okuta nla ti o wà ni Gibeoni, Amasa si ṣaju wọn. Joabu si di amùre si agbada rẹ̀ ti o wọ̀, o si sán idà rẹ̀ mọ idi, ninu akọ̀ rẹ̀, bi o si ti nlọ, o yọ jade.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí wọ́n dé ibi òkútà ńlá tí ó wà ní Gíbíónì, Ámásà sì ṣáájú wọn, Jóábù sì di àmùrè sí agbádá rẹ̀ tí ó wọ̀, ó sì sán idà rẹ̀ mọ́ ìdí, nínú àkọ̀ rẹ̀, bí ó sì ti ń lọ, ó yọ́ jáde.