2 Samuel 21:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní àkókò ìjọba Dafidi, ìyàn ńlá kan mú, fún odidi ọdún mẹta. Dafidi bá lọ wádìí ọ̀rọ̀ náà lọ́dọ̀ OLUWA. OLUWA sì dáhùn pé, “Saulu ati ìdílé rẹ̀ jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ìpànìyàn, nítorí pé ó pa àwọn ará Gibeoni.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
IYAN kan si mu ni ọjọ Dafidi li ọdun mẹta, lati ọdun de ọdun; Dafidi si bere lọdọ Oluwa, Oluwa si wipe, Nitori ti Saulu ni, ati nitori ile rẹ̀ ti o kún fun ẹ̀jẹ̀, nitoripe o pa awọn ara Gibeoni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìyàn kan sì mú lọ́jọ́ Dáfídì ní ọdún mẹ́ta, láti ọdún dé ọdún; Dáfídì sì béèrè lọ́dọ̀ OLÚWA, OLÚWA sì wí pé, Nítorí ti Ṣọ́ọ̀lù ni, àti nítorí ilé rẹ̀ tí ó kún fún ẹ̀jẹ̀, nítorí pé ó pa àwọn ará Gíbíónì.