2 Samuel 21:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Risipa, ọmọbinrin Aya, fi aṣọ ọ̀fọ̀ pa àtíbàbà fún ara rẹ̀ lórí òkúta, níbi tí òkú àwọn tí wọ́n pa wà. Ó wà níbẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè, títí di àkókò tí òjò bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀. Ní ojúmọmọ, kò jẹ́ kí àwọn ẹyẹ jẹ wọ́n ní ọ̀sán, kò sì jẹ́ kí àwọn ẹranko burúkú fọwọ́ kàn wọ́n lóru.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Rispa ọmọbinrin Aia si mu aṣọ ọfọ̀ kan, o si tẹ́ ẹ fun ara rẹ̀ lori àpata, ni ibẹrẹ ikore, titi omi fi dà si wọn lara lati ọrun wá, kò si jẹ ki awọn ẹiyẹ oju ọrun bà le wọn li ọsan, tabi awọn ẹranko igbẹ li oru.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Rísípà ọmọbìnrin Áíyà sì mú aṣọ ọ̀fọ̀ kan, ó sì tẹ́ fún ará rẹ̀ lórí àpáta ní ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè, títí omi fi dà sí wọn lára láti ọ̀run wá, kò sì jẹ́ kí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run bà lé wọn lọ́sán-an, tàbí àwọn ẹranko ìgbẹ́ lóru.