2 Samuel 21:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
ó lọ kó egungun Saulu, ati ti Jonatani, ọmọ rẹ̀, tí ó wà lọ́dọ̀ àwọn ará Jabeṣi-Gileadi. (Àwọn ará Jabeṣi ti jí àwọn egungun náà kó kúrò ní ìta gbangba, ní ààrin ìlú ní Beti Ṣani, níbi tí àwọn ará Filistia so wọ́n kọ́ sí, ní ọjọ́ tí wọ́n pa wọ́n ní òkè Giliboa.)
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si lọ o si ko egungun Saulu, ati egungun Jonatani ọmọ rẹ̀ kuro lọdọ awọn ọkunrin Jabeṣi-gileadi, awọn ti o ti ji wọn kuro ni ita Betṣani, nibiti awọn Filistini gbe so wọn rọ̀, nigbati awọn Filistini pa Saulu ni Gilboa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì sì lọ ó sì kó egungun Ṣọ́ọ̀lù, àti egungun Jónátánì ọmọ rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọkùnrin Jábéṣì-Gíléádì, àwọn tí ó jí wọn kúrò ní ìta Bẹti-Sánì, níbi tí àwọn Fílístínì gbé so wọ́n rọ̀, nígbà tí àwọn Fílístínì pa Sọ́ọ̀lù ní Gílíbóà.