2 Samuel 21:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n sin egungun Saulu, ati ti Jonatani, sinu ibojì Kiṣi, baba rẹ̀, ní Sela ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Bẹnjamini. Gbogbo ohun tí ọba pa láṣẹ ni wọ́n ṣe. Lẹ́yìn náà, ni Ọlọrun gbọ́ adura tí wọ́n ń gbà fún ilẹ̀ náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si sin egungun Saulu ati ti Jonatani ọmọ rẹ̀ ni ilẹ Benjamini, ni Sela, ninu iboji Kiṣi baba rẹ̀: nwọn si ṣe gbogbo eyi ti ọba pa li aṣẹ: lẹhin eyini Ọlọrun si gbà ẹbẹ nitori ilẹ na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì sin egungun Sọ́ọ̀lù àti ti Jònátánì ọmọ rẹ̀ ní ilé Bẹ́ńjámínì, ní Sélà, nínú ibojì Kíṣì baba rẹ̀: wọ́n sì ṣe gbogbo èyí tí ọba paláṣẹ: lẹ́yìn èyí ni Ọlọ́run si gba ẹ̀bẹ̀ nítorí ilẹ̀ náà.