2 Samuel 21:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ogun mìíràn tún bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ará Filistia ati àwọn ọmọ Israẹli. Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ sì lọ bá àwọn ará Filistia jagun. Bí wọ́n ti ń jà, àárẹ̀ mú Dafidi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ogun si tun wà larin awọn Filistini ati Israeli; Dafidi si sọkalẹ, ati awọn iranṣẹ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, o si ba awọn Filistini jà: o si rẹ̀ Dafidi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ogun sì tún wà láàrin àwọn Fílístínì àti Ísírẹ́lì; Dáfídì sì sọ̀kalẹ̀, àti àwọn ìránṣẹ rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì bá àwọn Fílístínì jà: ó sì rẹ Dáfídì.