2 Samuel 21:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn Abiṣai, ọmọ Seruaya, sáré wá láti ran Dafidi lọ́wọ́, ó kọlu òmìrán náà, ó sì pa á. Láti ìgbà náà ni àwọn ọmọ ogun Dafidi ti búra fún un pé, “A kò ní jẹ́ kí o bá wa lọ sí ojú ogun mọ́ kí á má baà pàdánù rẹ, nítorí pé ìwọ ni ìrètí Israẹli.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Abiṣai ọmọ Seruia si ràn a lọwọ, o si kọlu Filistini na, o si pa a. Nigbana ni awọn iranṣẹ Dafidi si bura fun u, pe, Iwọ kì yio si tun ba wa jade lọ si ibi ija mọ, ki iwọ ki o máṣe pa iná Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n Ábíṣáì ọmọ Sérúíà ràn án lọ́wọ́, ó sì kọlu Fílístínì náà, ó sì paá, Nígbà náà ni àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì sì búra fún un pé, “Ìwọ kì yóò sì tún bá wa jáde lọ sí ibi ìjà mọ́ kí iwọ má ṣe pa iná Ísírẹ́lì.”