2 Samuel 21:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn èyí, ogun mìíràn tún bẹ́ sílẹ̀ pẹlu àwọn ará Filistia, ní Gobu, ninu ogun yìí ni Sibekai ará Huṣa ti pa Safu, ọ̀kan ninu àwọn ìran òmìrán.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, lẹhin eyi, ija kan si tun wà lãrin awọn Israeli ati awọn Filistini ni Gobu: nigbana ni Sibbekai ara Huṣa pa Safu, ẹniti iṣe ọkan ninu awọn òmirán.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn èyí, ìjà kan sì tún wà láàrin àwọn Ísírẹ́lì àti àwọn Fílístínì ní Góbù: nígbà náà ni Síbékáì ará Húṣà pa Sáfù, ẹni tí í ṣe ọ̀kan nínú àwọn òmìrán.