2 Samuel 21:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ogun mìíràn tún bẹ́ sílẹ̀ pẹlu àwọn ará Filistia kan náà, ní Gobu. Ninu ogun yìí ni Elihanani ọmọ Jaareoregimu, ará Bẹtilẹhẹmu, ti pa Goliati, ará Giti, ẹni tí ọ̀pá ọ̀kọ̀ rẹ̀ nípọn tó igi òfì tí àwọn obinrin fi máa ń hun aṣọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ija kan si tun wà ni Gobu lãrin awọn Israeli ati awọn Filistini, Elhanani ọmọ Jairi ara Betlehemu si pa arakunrin Goliati ara Gati, ẹniti ọpá ọ̀kọ rẹ̀ dabi idabú igi ti a fi hun aṣọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìjà kan sì tún wà ní Góbù láàrin àwọn Ísírẹ́lì àti àwọn Fílístínì, Élíhánánì ọmọ Jáírì ará Bẹ́tílẹ́hẹ́mù sì pa arákùnrin Gòláyátì, ará Gátì, ẹni tí ọ̀pá ọ̀kọ̀ rẹ̀ dàbí ìdúbú igi tí a fi ń hun aṣọ.