2 Samuel 21:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ará Gibeoni kì í ṣe ara àwọn ọmọ Israẹli. Ara àwọn ará Amori tí wọ́n ṣẹ́kù ni wọ́n. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ Israẹli ti ṣèlérí pé àwọn kò ní pa wọ́n, sibẹsibẹ Saulu gbìyànjú láti pa wọ́n run, nítorí ìtara rẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli ati Juda.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba si pe awọn ara Gibeoni, o si ba wọn sọ̀rọ: awọn ara Gibeoni ki iṣe ọkan ninu awọn ọmọ Israeli, ṣugbọn nwọn jẹ awọn ti o kù ninu awọn ọmọ Amori; awọn ọmọ Israeli si ti bura fun wọn: Saulu si nwá ọ̀na ati pa wọn ni itara rẹ̀ fun awọn ọmọ Israeli ati Juda.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba sì pe àwọn ará Gíbíónì, ó sì bá wọn sọ̀rọ̀; àwọn ará Gíbíónì kì í ṣe ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ṣùgbọ́n wọ́n jẹ́ àwọn tí ó kù nínú àwọn ọmọ Ámórì; àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ti búra fún wọn: Ṣọ́ọ̀lù sì ń wá ọ̀nà àti pa wọ́n ní ìtara rẹ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti Júdà.