2 Samuel 21:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ogun mìíràn tún bẹ́ sílẹ̀ ní Gati. Òmìrán kan wà níbẹ̀ tí ó fẹ́ràn ogun jíjà pupọ, ìka mẹfa mẹfa ni ó ní ní ọwọ́ kọ̀ọ̀kan, ati ẹsẹ̀ kọ̀ọ̀kan; ìka ọwọ́ ati ti ẹsẹ̀ rẹ̀ jẹ́ mẹrinlelogun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ija kan si tun wà ni Gati, ọkunrin kan si wà ti o gùn pupọ, o si ni ika mẹfa li ọwọ́ kan, ati ọmọ-ẹsẹ mẹfa li ẹsẹ kan, apapọ̀ rẹ̀ si jẹ mẹrinlelogun; a si bi on na li òmirán.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìjà kan sì tún wà ní Gátì, ọkùnrin kan sì wà tí ó ga púpọ̀, ó sì ní ìka mẹ́fà ní ọwọ́ kan, àti ọmọ ẹṣẹ̀ mẹ́fà ní ẹṣẹ̀ kan, àpapọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ mẹ́rìnlélógún; a sì bí òun náà ní òmìrán.