2 Samuel 21:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n dá a lóhùn pé, “Aáwọ̀ tí ó wà láàrin àwa ati Saulu ati ìdílé rẹ̀, kì í ṣe ohun tí a lè fi wúrà ati fadaka parí, a kò sì fẹ́ pa ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ Israẹli.” Dafidi bá tún bèèrè pé, “Kí ni ẹ wá fẹ́ kí n ṣe fun yín?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ara Gibeoni si wi fun u pe, Awa kò ni fi fadaka tabi wura ti Saulu ati ti idile rẹ̀ ṣe, bẹ̃ni a kò si fẹ ki ẹ pa ẹnikan ni Israeli. O si wipe, eyi ti ẹnyin ba wi li emi o ṣe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ará Gíbíónì sì wí fún un pé, “Kì í ṣe ọ̀rọ̀ fàdákà tàbí wúrà láàrin wa àti Ṣọ́ọ̀lù tàbí ìdílé rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì fẹ́ kí ẹ pa ẹnìkan ní Ísírẹ́lì.” Dáfídì sì wí pé, “Èyí tí ẹ̀yin bá wí ni èmi ó ṣe?”