2 Samuel 21:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn ó mú Arimoni ati Mẹfiboṣẹti àwọn ọmọkunrin mejeeji tí Risipa, ọmọ Aya, bí fún Saulu; ó sì tún mú àwọn ọmọ marun-un tí Merabu, ọmọbinrin Saulu, bí fún Adirieli ọmọ Basilai ará Mehola.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba si mu awọn ọmọkunrin mejeji ti Rispa ọmọbinrin Aia bi fun Saulu, ani Armoni ati Mefiboṣeti: ati awọn ọmọkunrin mararun ti Merabu, ọmọbinrin Saulu, awọn ti o bi fun Adrieli ọmọ Barsillai ara Meholati.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba sì mú àwọn ọmọkùnrin méjèèjì tí Rísípà ọmọbìnrin Áíyà bí fún Ṣọ́ọ̀lù, àní Ámónì àti Méfíbóṣétì àwọn ọmọkùnrin máràrùn ti Mérábù, ọmọbìnrin Ṣọ́ọ̀lù, àwọn tí ó bí fún Ádíríélì ọmọ Básílíà ará Méhólátì.