2 Samuel 21:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Dafidi kó wọn lé àwọn ará Gibeoni lọ́wọ́, àwọn ará Gibeoni sì so wọ́n kọ́ sórí igi, lórí òkè níwájú OLUWA, àwọn mejeeje sì kú papọ̀. Àkókò tí wọ́n kú yìí jẹ́ àkókò ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè ọkà baali nígbà tí àkókò ìrúwé fẹ́rẹ̀ kásẹ̀ nílẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si fi wọn le awọn ara Gibea lọwọ, nwọn si so wọn rọ̀ lori oke niwaju Oluwa: awọn mejeje si ṣubu lẹ̃kan, a si pa wọn ni igbà ikore, ni ibẹrẹ ikore ọka-barle.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì fi wọ́n lé àwọn ará Gíbéà lọ́wọ́, wọ́n sì so wọ́n rọ̀ lórí òkè níwájú OLÚWA: àwọn méjèèjì sì ṣubú lẹ́ẹ̀kan, a sì pa wọ́n ní ìgbà ìkórè, ní ìbẹ̀rẹ̀, ìkórè ọkà-báálì.