2 Samuel 22:44 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ìwọ ni o gbà mí lọ́wọ́ ìjà àwọn eniyan mi, o sì mú kí ìjọba mi dúró lórí àwọn orílẹ̀ èdè; àwọn eniyan tí n kò mọ̀ rí di ẹni tí ó ń sìn mí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ si gbà mi kuro lọwọ ijà awọn enia mi, iwọ pa mi mọ ki emi ki o le ṣe olori awọn ajeji orilẹ-ède: awọn enia ti emi kò ti mọ̀ yio ma sìn mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ìwọ sì gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìjà àwọn ènìyàn mi, ìwọ pá mí mọ́ ki èmi lè ṣe olórí àwọn àjèjì orílẹ̀-èdè. Àwọn ènìyàn tí èmi kòì tí mọ̀ yóò máa sìn mí.