2 Samuel 23:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn Eleasari dúró gbọningbọnin, ó sì bá àwọn ará Filistia jà títí tí ọwọ́ rẹ̀ fi wo koko mọ́ idà rẹ̀, tí kò sì le jù ú sílẹ̀ mọ́. OLUWA ja àjàṣẹ́gun ńlá ní ọjọ́ náà. Lẹ́yìn tí ogun náà parí ni àwọn ọmọ ogun Israẹli tó pada sí ibi tí Eleasari wà, tí wọ́n lọ kó àwọn ohun ìjà tí ó wà lára àwọn tí ogun pa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si dide, o si kọlù awọn Filistini titi ọwọ́ fi kún u, ọwọ́ rẹ̀ si lẹ̀ mọ idà: Oluwa si ṣiṣẹ igbala nla li ọjọ na; awọn enia si yipada lẹhin rẹ̀ lati ko ikogun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Òun sì dìde, ó sì kọlu àwọn Fílístínì títí ọwọ́ fi kún un, ọwọ́ rẹ̀ sì lẹ̀ mọ́ idà; OLÚWA sì ṣiṣẹ́ ìgbàlà ńlá lọ́jọ́ náà, àwọn ènìyàn sì padà bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀ láti kó ìkógun.