2 Samuel 23:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹnìkẹta ninu àwọn akọni náà ni Ṣama, ọmọ Agee, ará Harari. Ní àkókò kan, àwọn ará Filistia kó ara wọn jọ sí Lehi, níbi tí oko ewébẹ̀ kan wà. Àwọn ọmọ ogun Israẹli sá fún àwọn ará Filistia,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹniti o tẹ̀le e ni Samma ọmọ Agee ará Harari. Awọn Filistini si ko ara wọn jọ lati piyẹ, oko kan si wà nibẹ ti o kún fun ẹwẹ: awọn enia si sa kuro niwaju awọn Filistini.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹni tí ó tẹ̀lé e ni Sámímà ọmọ Ágè ará Hárárì, àwọn Fílístínì sì kó ara wọn jọ ní Léhì, oko kan tí ó kún fun ẹwẹ: àwọn ènìyàn sì sá kúrò níwájú àwọn Fílístínì.