2 Samuel 23:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí àkókò ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè súnmọ́ tòsí, mẹta ninu àwọn ọgbọ̀n akọni náà lọ sí inú ihò àpáta tí ó wà ní Adulamu, níbi tí Dafidi wà nígbà náà, nígbà tí ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun Filistini pàgọ́ wọn sí àfonífojì Refaimu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn mẹta ninu ọgbọ̀n olori si sọkalẹ, nwọn si tọ Dafidi wá li akoko ikore ninu iho Adullamu: ọ̀wọ́ awọn Filistini si do ni afonifoji Refaimu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn mẹ́ta nínú ọgbọ̀n olórí sì sọkalẹ̀, wọ́n sì tọ Dáfídì wá ní àkókò ìkórè nínú ihò Ádúlámù: ọ̀wọ́ àwọn Fílístínì sì dó sí àfonífojì Réfáímù.