2 Samuel 23:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Arakunrin Joabu, tí ń jẹ́ Abiṣai, ọmọ Seruaya ni aṣiwaju fún “Àwọn Ọgbọ̀n Akọni Olókìkí.” Ó fi idà rẹ̀ pa ọọdunrun eniyan, nípa bẹ́ẹ̀, ó di olókìkí láàrin wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Abiṣai, arakunrin Joabu, ọmọ Seruia, on na ni pataki ninu awọn mẹta. On li o si gbe ọ̀kọ rẹ̀ soke si ọ̃dunrun enia, o si pa wọn, o si ni orukọ ninu awọn mẹtẹta.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ábíṣáì, arákùnrin Jóábù, ọmọ Sérúíà, òun náà ni pàtàkì nínú àwọn mẹ́ta. Òun ni ó sì gbé ọ̀kọ̀ rẹ̀ sókè sí ọ̀ọ́dúnrún ènìyàn, ó sì pa wọ́n, ó sì ní orúkọ nínú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta.