2 Samuel 23:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún arọmọdọmọ mi níwájú Ọlọrun, nítorí pé, ó ti bá mi dá majẹmu ayérayé nípa ohun gbogbo, majẹmu tí kò lè yipada, ati ìlérí tí kò ní yẹ̀. Yóo ṣe ohun tí mo fẹ́ fún mi. Yóo ràn mí lọ́wọ́, yóo fún mi ní ìfẹ́ ọkàn mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lõtọ ile mi kò ri bẹ niwaju Ọlọrun, ṣugbọn o ti ba mi da majẹmu ainipẹkun, ti a tunṣe ninu ohun gbogbo, ti a si pamọ: nitoripe gbogbo eyi ni igbala mi, ati gbogbo ifẹ mi, ile mi kò le ṣe ki o ma dagbà?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Lóòtọ́ ilé mi kò rí bẹ́ẹ̀ níwájú Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ó ti bá mi dá májẹ̀mú àìnípẹ̀kun, tí a túnṣe nínú ohun gbogbo, tí a sì pamọ́; nítorí pé gbogbo èyí ni ìgbàlà, àti gbogbo ìfẹ́ mi, ilé mi kò lè ṣe kí ó má dágbà.