2 Samuel 23:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹni tí ó tẹ̀lé e ni, Eleasari, ọmọ Dodo, ti ìdílé Ahohi, ó wà pẹlu Dafidi nígbà tí wọ́n pe àwọn ará Filistia níjà, tí wọ́n kó ara wọn jọ fún ogun, tí àwọn ọmọ ogun Israẹli sì sá sẹ́yìn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹniti o tẹ̀le e ni Eleasari ọmọ Dodo ara Ahohi, ọkan ninu awọn alagbara ọkunrin mẹta ti o wà pẹlu Dafidi, nigbati nwọn pe awọn Filistini ni ijà, awọn ti o kó ara wọn jọ si ibẹ lati jà, awọn ọmọkunrin Israeli si ti lọ kuro:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹni tí ó tẹ̀lé e ni Élíásárì ọmọ Dódò ará Áhóhì, ọ̀kan nínú àwọn alágbára ọkùnrin mẹ́ta ti wà pẹ̀lú Dáfídì, nígbà tí wọ́n pe àwọn Fílístínì ní ìjà, àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sì ti lọ kúrò.