2 Samuel 24:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn lẹ́yìn ìgbà tí Dafidi ka àwọn eniyan náà tán, ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí dà á láàmú. Ó bá wí fún OLUWA pé, “Ohun tí mo ṣe yìí burú gan-an, ẹ̀ṣẹ̀ ńlá gbáà ni. Jọ̀wọ́, dáríjì èmi iranṣẹ rẹ, ìwà òmùgọ̀ gbáà ni mo hù.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ̀rí ọkàn si bẹrẹ si da Dafidi lãmú lẹhin igbati o kà awọn enia na tan. Dafidi si wi fun Oluwa pe, Emi ṣẹ̀ gidigidi li eyi ti emi ṣe: ṣugbọn, emi bẹ̀ ọ, Oluwa, fi ẹ̀ṣẹ iranṣẹ rẹ jì i, nitoripe emi huwà aṣiwere gidigidi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àyà Dáfídì sì gbọgbẹ́ lẹ́yìn ìgbà tí ó ka àwọn ènìyàn náà tán. Dáfídì sì wí fún OLÚWA pé, “Èmi ṣẹ̀ gidigidi ní èyí tí èmi ṣe: ṣùgbọ́n, èmi bẹ̀ ọ, OLÚWA, fi ẹ̀ṣẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ jìn ní, nítorí pé èmi hùwà aṣiwèrè gidigidi!”