2 Samuel 24:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gadi bá lọ sọ ohun tí OLUWA wí fún Dafidi. Ó bèèrè pé, “Èwo ni o fẹ́ yàn ninu mẹtẹẹta yìí, ekinni, kí ìyàn mú ní ilẹ̀ rẹ fún ọdún mẹta; ekeji, kí o máa sá fún àwọn ọ̀tá rẹ fún oṣù mẹta; ẹkẹta, kí àjàkálẹ̀ àrùn jà fún ọjọ́ mẹta ní gbogbo ilẹ̀ rẹ? Rò ó dáradára, kí o sì sọ èyí tí o fẹ́, kí n lọ sọ fún OLUWA.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gadi si tọ Dafidi wá, o si bi i lere pe, Ki iyàn ọdun meje ki o tọ̀ ọ wá ni ilẹ rẹ bi? tabi ki iwọ ki o ma sá li oṣu mẹta niwaju awọn ọta rẹ, nigbati nwọn o ma le ọ? tabi ki arùn iparun ijọ mẹta ki o wá si ilẹ rẹ? rõ nisisiyi, ki o si mọ̀ èsi ti emi o mu pada tọ̀ ẹniti o rán mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gádì sì tọ Dáfídì wá, ó sì bi í léèrè pé, “Kí ìyàn ọdún méje ó tọ̀ ọ́ wá ní ilẹ̀ rẹ bí? Tàbí kí ìwọ máa sá ní oṣù mẹ́ta níwájú àwọn ọ̀ta rẹ, nígbà tí wọn ó máa lé ọ? Tàbí kí àrun ìparun ijọ́ mẹ́ta ó wá sí ilẹ̀ rẹ? Ròó nísinsin yìí, kí o sì mọ èsì tí èmi ó mú padà tọ ẹni tí ó rán mi.”