2 Samuel 24:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Dafidi dá Gadi lóhùn pé, “Ìdààmú ńlá ni ó dé bá mi yìí, ṣugbọn ó yá mi lára kí OLUWA jẹ wá níyà ju pé kí ó fi mí lé eniyan lọ́wọ́ lọ; nítorí pé, aláàánú ni OLUWA.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si wi fun Gadi pe, Iyọnu nla ba mi: jẹ ki a fi ara wa le Oluwa li ọwọ́; nitoripe ãnu rẹ̀ pọ̀: ki o má si ṣe fi mi le enia li ọwọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì sì wí fún Gádì pé, “Ìyọnu ńlá bá mi. Jẹ́ kí a fi ara wa lé OLÚWA lọ́wọ́; nítorí pé àánú rẹ̀ pọ̀; kí ó má sì ṣe fi mí lé ènìyàn lọ́wọ́.”