2 Samuel 24:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, OLUWA fi àjàkálẹ̀ àrùn bá Israẹli jà. Ó bẹ̀rẹ̀ láti òwúrọ̀ títí di àkókò tí ó yàn jákèjádò ilẹ̀ Israẹli. Láti Dani títí dé Beeriṣeba, gbogbo àwọn tí ó kú jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹta ati ẹgbaarun (70,000).
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa si rán arùn iparun si Israeli lati owurọ̀ titi de akoko ti a da: ẹgbã marundilogoji enia si kú ninu awọn enia na lati Dani titi fi de Beerṣeba.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA sì rán àrùn ìparun sí Ísírẹ́lì láti òwúrọ̀ títí dé àkókò tí a dá: ẹgbàá márùndínlógójì ènìyàn sì kú nínú àwọn ènìyàn náà láti Dánì títí fi dé Bééríṣébà.