2 Samuel 24:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí angẹli OLUWA náà fẹ́ bẹ̀rẹ̀ láti máa pa Jerusalẹmu run, OLUWA yí ọkàn pada nípa jíjẹ tí ó ń jẹ àwọn eniyan náà níyà. Ó bá wí fún angẹli náà pé, “Ó tó gẹ́ẹ́, dáwọ́ dúró.” Níbi ìpakà Arauna ará Jebusi kan ni angẹli náà wà nígbà náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati angeli na si nawọ́ rẹ̀ si Jerusalemu lati pa a run, Oluwa si kãnu nitori ibi na, o si sọ fun angeli ti npa awọn enia na run pe, O to: da ọwọ́ rẹ duro wayi. Angeli Oluwa na si wà nibi ipaka Arauna ara Jebusi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ańgẹ́lì náà sì nawọ́ rẹ̀ sí Jérúsálẹ́mù láti pa á run, OLÚWA sì káàánú nítorí ibi náà, ó sì sọ fún ańgẹ́li tí ń pá àwọn ènìyàn náà run pé, “Ó tó, dá ọwọ́ rẹ dúró wàyìí!” Ańgẹ́lì OLÚWA náà sì wà níbi ìpakà Áráúnà ará Jèbúsì.