2 Samuel 24:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí Dafidi rí angẹli tí ó ń pa àwọn eniyan náà, ó wí fún OLUWA pé, “Èmi ni mo ṣẹ̀, èmi ni mo ṣe burúkú. Kí ni àwọn eniyan wọnyi ṣe? Èmi ati ìdílé baba mi ni ó yẹ kí ó jẹ níyà.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si wi fun Oluwa nigbati o ri angeli ti nkọlu awọn enia pe, Wõ, emi ti ṣẹ̀, emi si ti huwà buburu: ṣugbọn awọn agutan wọnyi, kini nwọn ha ṣe? jẹ ki ọwọ́ rẹ, emi bẹ̀ ọ, ki o wà li ara mi, ati li ara idile baba mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì sì wí fún OLÚWA nígbà tí ó rí ańgẹ́li tí ń kọlu àwọn ènìyàn pé, “Wò ó, èmi ti ṣẹ̀, èmi sì ti hùwà búburú ṣùgbọ́n àwọn àgùntàn wọ̀nyí, kín ni wọ́n ha ṣe? Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ, èmi bẹ̀ ọ́, kí ó wà lára mi àti ìdílé baba mi.”