2 Samuel 24:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Dafidi bá pàṣẹ fún Joabu, ati àwọn ọ̀gágun rẹ̀, tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀, ó ní, “Ẹ lọ sí gbogbo ẹ̀yà Israẹli, láti Dani títí dé Beeriṣeba, kí ẹ sì ka gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà níbẹ̀, kí n lè mọ iye wọn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba si wi fun Joabu olori ogun, ti mbẹ lọdọ rẹ̀ pe, Lọ nisisiyi si gbogbo ẹyà Israeli lati Dani titi de Beerṣeba, ki ẹ si kà iye awọn enia, ki emi le mọ̀ iye awọn enia na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba sì wí fún Jóábù Olórí ogun, tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Lọ ní ìsinsìnyìí sí gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì láti Dánì títí dé Bíásébà, kí ẹ sì ka iye àwọn ènìyàn, kí èmi lè mọ iye àwọn ènìyàn náà!”