2 Samuel 24:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí Arauna wo ìsàlẹ̀, ó rí ọba ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ tí wọn ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó lọ pàdé rẹ̀, ó kí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ó sì dojúbolẹ̀ níwájú rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Arauna si wò, o si ri ọba ati awọn iranṣẹ rẹ̀ mbọ̀ wá ọdọ rẹ̀: Arauna si jade, o si wolẹ niwaju ọba o si doju rẹ̀ bolẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Áráúnà sì wò, ó sì rí ọba àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ń bọ̀ wá lọ́dọ̀ rẹ̀: Áráúnà sì jáde, ó sì wólẹ̀ níwájú ọba ó sì dojú rẹ̀ bolẹ̀.