2 Samuel 24:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó bi í pé, “Ṣé kò sí, tí oluwa mi, ọba, fi wá sọ́dọ̀ èmi, iranṣẹ rẹ̀?” Dafidi dá a lóhùn pé, “Ilẹ̀ ìpakà rẹ ni mo fẹ́ rà, mo fẹ́ tẹ́ pẹpẹ kan fún OLUWA, kí àjàkálẹ̀ àrùn yìí lè dáwọ́ dúró.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Arauna si wipe, Nitori kili oluwa mi ọba ṣe tọ iranṣẹ rẹ̀ wá? Dafidi si dahùn pe, Lati rà ibi ipaka nì lọwọ rẹ, lati tẹ́ pẹpẹ kan fun Oluwa, ki arùn iparun ki o le da li ara awọn enia na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Áráúnà sì wí pé, “Nítorí kín ni OLÚWA mi ọba ṣe tọ ìránṣẹ́ rẹ̀ wá?” Dáfídì sì dáhùn pé, “Láti ra ibi ìpakà rẹ lọ́wọ́ rẹ, láti tẹ́ pẹpẹ kan fún OLÚWA, kí àrùn ìparun lè dá lára àwọn ènìyàn náà.”