2 Samuel 24:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Arauna dá a lóhùn pé, “Máa mú un, kí o sì mú ohunkohun tí o bá fẹ́ fi rúbọ sí OLUWA. Akọ mààlúù nìwọ̀nyí, tí o lè fi rú ẹbọ sísun sí OLUWA. Àwọn àjàgà wọn nìwọ̀nyí, ati àwọn igi ìpakà tí o lè lò fún igi ìdáná.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Arauna si wi fun Dafidi pe, Jẹ ki oluwa mi ọba ki o mu eyi ti o dara li oju rẹ̀, ki o si fi i rubọ: wõ, malu niyi lati fi ṣe ẹbọ sisun, ati ohun elo ipaka, ati ohun elo miran ti malu fun igi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Áráúnà sì wí fún Dáfídì pé, “Jẹ́ kí OLÚWA mi ọba ó mú èyí tí ó dára lójú rẹ̀, kí o sì fi í rúbọ: wò ó, màlúù nìyìí láti fi ṣe ẹbọ sísun, àti ohun èlò ìpakà, àti ohun èlò mìíràn ti màlúù fún igi.