2 Samuel 24:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn Joabu bi ọba léèrè pé, “Kí OLUWA Ọlọrun rẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli pọ̀ jù báyìí lọ, ní ìlọ́po ọ̀nà ọgọrun-un (100), nígbà tí oluwa mi ṣì wà láàyè; ṣugbọn, kí ló dé tí kabiyesi fi fẹ́ ka àwọn eniyan wọnyi?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Joabu si wi fun ọba pe, Ki Oluwa Ọlọrun rẹ ki o fi kún iye awọn enia na, iyekiye ki o wu ki wọn jẹ, li ọrọrún; oju oluwa mi ọba yio si ri i: ṣugbọn ẽtiṣe ti oluwa mi ọba fi fẹ nkan yi?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jóábù sì wí fún ọba pé, “Kí OLÚWA Ọlọ́run rẹ fi kún ìye àwọn ènìyàn náà, ìyekíye kí ó wù kí wọn jẹ́, ní ọrọrún, ojú OLÚWA mi ọba yóò sì rí i: ṣùgbọ́n èétiṣe tí OLÚWA mi ọba fi fẹ́ nǹkan yìí?”