2 Samuel 24:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Joabu sọ iye àwọn eniyan tí ó kà fún ọba: Ogoji ọ̀kẹ́ (800,000) ni àwọn ọkunrin tí wọ́n tó ogun jà ní ilẹ̀ Israẹli, àwọn ti ilẹ̀ Juda sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹẹdọgbọn (500,000).
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Joabu si fi iye ti awọn enia na jasi le ọba lọwọ: o si jẹ oji ọkẹ ọkunrin alagbara ní Israeli, awọn onidà: awọn ọkunrin Juda si jẹ ọkẹ mẹ̃dọgbọn enia.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jóábù sì fi iye tí àwọn ènìyàn náà jásí lé ọba lọ́wọ́: ó sì jẹ́ òjì ọ̀kẹ́ ọkùnrin alágbára ní Ísírẹ́lì, àwọn onídà: àwọn ọkùnrin Júdà sì jẹ́ ọkẹ mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ènìyàn.