2 Samuel 3:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Dafidi bá dáhùn pé, “Ó dára, n óo bá ọ dá majẹmu. Ṣugbọn nǹkankan ni mo fẹ́ kí o ṣe, o kò ní fi ojú kàn mí, àfi bí o bá mú Mikali ọmọbinrin Saulu lọ́wọ́ nígbà tí o bá ń bọ̀ wá rí mi.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si wi pe, O dara, emi o ba ọ ṣe adehun: ṣugbọn nkan kan li emi o bere lọwọ rẹ, eyini ni, Iwọ ki yio ri oju mi, afi bi iwọ ba mu Mikali ọmọbinrin Saulu wá, nigbati iwọ ba mbọ, lati ri oju mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Òun sì wí pé, “Ó dárá, èmi ó bá ọ ṣe àdéhùn: ṣùgbọ́n ohun kan ni èmi ó béèrè lọ́wọ́ rẹ, èyí ni pé, ìwọ kì yóò rí ojú mi, àfi bí ìwọ bá kọ́ mú Míkálì ọmọbìnrin Ṣọ́ọ̀lù wá, nígbà tí ìwọ bá wá, láti rí ojú mi.”