2 Samuel 3:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àkókò nìyí láti ṣe ohun tí ẹ ti fẹ́ ṣe, nítorí pé OLUWA ti ṣe ìlérí fún Dafidi pé Dafidi ni òun óo lò láti gba àwọn ọmọ Israẹli kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Filistia ati gbogbo àwọn ọ̀tá wọn yòókù.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ, ẹ ṣe e: nitoriti Oluwa ti sọ fun Dafidi pe, Lati ọwọ́ Dafidi iranṣẹ mi li emi o gbà Israeli enia mi là kuro lọwọ awọn Filistini ati lọwọ gbogbo awọn ọta wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ǹjẹ́, ẹ ṣe: nítorí tí OLÚWA ti sọ fún Dáfídì pé, ‘Láti ọwọ́ Dáfídì ìránṣẹ mi lémi ó gba Isíraẹ́lì ènìyàn mi là kúrò lọ́wọ́ àwọn Fílístínì àti lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀taa wọn.’ ”